Oriki

 

Oriki Ibeji

Ejire ara Isokun

Edun A gbori igi regrege
Winino winini loju orogun
Eji woro loju iya e
O be kisi be kese
O be sile elekisa
O so o dalaso
Okan mo ni n o bi
Eji lo wole to mi
Bu mi ki nba o rele
Yin mi ki npada leyin re
Nijo ejire ti daye ko jale ri
Oju oloko ni se je tie
Mo lepo nile
Mo lewa loode
Ejire eelaki maa bo lodo mi
Ireke mi ree 
Aadun mi ree 
Mo fe bo ibeji oro
Oniruuru omo lo nbe laye
Ninu omo to je abami
La gbe ri ibeji laarin won
Eni ejiree nwuu bi
Ki o yaa niwa tutu
Tori pe osonu ile ko bi ejire 
Oninuure ni bedun
Ejire okin maa so mi lokun lona ofun 
Iya onikaluku won o so kale
Won abimo won okan soso pere
Eni oninuure lOlorun oba nfun lore
Eyin ko mo pe ore lejire ara isokun
Iyawo mi lejo 
Emi naa le sodi wuke
Ejire oriyaki maa bo lodo wa
Atike atige laa fi sike ibeji
Atowo atiyi lejire fii sike eni
Oga lejire oriyaki laarin awon omo to nbe laye gbogbo